Bí ó ti jẹ́ pé ṣíṣe àkíyèsí iyì tó jẹ́ àbímọ́ fún ẹ̀dá àti ìdọ́gba ẹ̀tọ́ tí kò ṣeé mú kúrò tí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní, ni òkúta ìpìlẹ̀ fún òmìnira, ìdájọ́ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé,
Whereas recognition of the inherent dignity and of the equal and inalienable rights of all members of the human family is the foundation of freedom, justice and peace in the world,
Bí ó ti jẹ́ pé àìka àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sí àti ìkẹ́gàn àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ti ṣe okùnfà fún àwọn ìwà búburú kan, tó mú ẹ̀rí-ọkàn ẹ̀dá gbọgbẹ́, tó sì jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrọ̀ sísọ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wọ́n gbọ́, òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀rù àti òmìnira lọ́wọ́ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lọ lọ́kàn àwọn ọmọ-èniyàn,
Whereas disregard and contempt for human rights have resulted in barbarous acts which have outraged the conscience of mankind, and the advent of a world in which human beings shall enjoy freedom of speech and belief and freedom from fear and want has been proclaimed as the highest aspiration of the common people,
Bí ó ti jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì kí a dáàbò bo àwọn ẹ̀tó ọmọnìyàn lábẹ́ òfin, bí a kò bá fẹ́ ti àwọn ènìyàn láti kọjú ìjà sí ìjọba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ọ̀nà àbáyọ mìíràn fún wọn láti bèèrè ẹ̀tọ́ wọn,
Whereas it is essential, if man is not to be compelled to have recourse, as a last resort, to rebellion against tyranny and oppression, that human rights should be protected by the rule of law,
Bí ó ti jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbáṣepọ̀ ti ọ̀rẹ́-sí-ọ̀rẹ́ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
Whereas it is essential to promote the development of friendly relations between nations,
Bí ó ti jẹ́ pé gbogbo ọmọ Àjọ-ìsọ̀kan orílẹ̀-èdè àgbáyé tún ti tẹnu mọ́ ìpinnu tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìwé àdéhùn wọn, pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí, ìgbàgbọ́ nínú iyì àti ẹ̀yẹ ẹ̀dá ènìyàn, àti ìgbàgbọ́ nínú ìdọ́gba ẹ̀tọ́ láàrin ọkùnrin àti obìnrin, tó sì jẹ́ pé wọ́n tún ti pinnu láti ṣe ìgbélárugẹ ìtẹ̀síwájú àwùjọ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé-ayé rere ẹ̀dá ti lè gbòòrò sí i,
Whereas the peoples of the United Nations have in the Charter reaffirmed their faith in fundamental human rights, in the dignity and worth of the human person and in the equal rights of men and women and have determined to promote social progress and better standards of life in larger freedom,
Bí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ-ìsọ̀kan orílẹ̀-èdè àgbáyé ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fọwọ́ṣowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Àjọ náà, kí won lè jọ ṣe àṣeyege nípa àmúṣẹ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti òmìnira ẹ̀dá tó jẹ́ kò-ṣeé-má-nìí àti láti rí i pé à ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ náà káríayé,
Whereas Member States have pledged themselves to achieve, in cooperation with the United Nations, the promotion of universal respect for and observance of human rights and fundamental freedoms,
Bí ó ti jẹ́ pé àfi tí àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọ̀nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmúṣẹ ẹ̀jẹ́ yìí ní kíkún,
Whereas a common understanding of these rights and freedoms is of the greatest importance for the full realization of this pledge,
Ní báyìí,
Now, therefore,
Àpapọ̀ ìgbìmọ̀ Àjọ-ìsọ̀kan orílẹ̀-èdè àgbáyé
The General Assembly,
ṣe ìkéde káríayé ti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, gẹ́gẹ́ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo ẹ̀dá àti orílẹ̀-èdè jọ ń lépa lọ́nà tó jẹ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan láwùjọ yóò fi ìkéde yìí sọ́kàn, tí wọn yóò sì rí i pé àwọn lo ètò-ìkọ́ni àti ètò-ẹ̀kọ́ láti ṣe ìgbélárugẹ ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọ̀nyí. Bákan náà, a gbọdọ̀ rí àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè mú ìlọsíwájú bá orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo tàbí àwọn orílẹ̀-èdè sí ara wọn, kí a sì rí i pé a fi ọ̀wọ̀ tó jọjú wọ àwọn òfin wọ̀nyí, kí àmúlò wọn sì jẹ́ káríayé láàrin àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọmọ Àjọ-ìsọ̀kan àgbáyé fúnra wọn àti láàrin àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè mìíràn tó wà lábẹ́ àṣẹ wọn.
Proclaims this Universal Declaration of Human Rights as a common standard of achievement for all peoples and all nations, to the end that every individual and every organ of society, keeping this Declaration constantly in mind, shall strive by teaching and education to promote respect for these rights and freedoms and by progressive measures, national and international, to secure their universal and effective recognition and observance, both among the peoples of Member States themselves and among the peoples of territories under their jurisdiction.